Èrò
Òṣèlú Jẹgúdú Jẹrá Ni Òṣèlú “Ìbàràpákan”: Ohun Àbùkù Ńlá Gbáà Sì Ni
Bí ìdìbò ọdún 2023 tí ń sún mọ́le, onírúurú àwọn olóṣèlú àti àwọn tí kò ní ìkólèkàn ará ìlú lọ́kàn ni wọ́n ti ń fi ìfẹ́ hàn sí oríṣiríṣi ipò nínú òṣèlú.
Ó jẹ́ ohun tí ó bani nínú jẹ́ púpọ̀ láti rí pé òṣèlú “tẹni bàjẹ́ kò kàn mí” ni òṣèlú tí ó dórí igbá. Èyí sì ti fi àyè gba àwọn kọ̀lọ̀rànsí ẹ̀dá àti àwọn aláìní kan ṣe láti di oríṣiríṣi ipò mú tí wọn sì ti fẹ́ sọọ́ di oyè ájẹwọ̀.
Ọmọ wa ni, ẹ jẹ́ kó ṣeé tí yí dánde ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni a gbójú okùn lé wọn kò jẹni agba. Kódà òwe Yorùbá tó ní ọmọ àlè èèyàn ní kọ̀dí síta máa tọ̀ sí ilé ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ aláìní ìtìjú ló wá pọ̀ báyìí nínú àwọn táa pè lọ́mọ bẹ́ẹ̀ kìí sì ṣe pé aráàlú dákẹ.
Peoplesconscience.com tí kọ̀wé láì mòye ìgbà lórí Dókítà Anthony Adebayo Adepoju àti ìwà ànìkànjopón rè pàápàá jù lọ lórí ọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè agbègbè rè ní Ìbàràpá.
Lọ́wọ́ báyìí, Dókítà Anthony Adebayo Adepoju ni alága àjọ tó ń rí sì ọ̀rọ̀ omi ẹ̀rọ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ó sì tún jẹ́ bàbà ìsàlè fún àwọn aláàbọ̀ ẹ̀kọ́ tó di ipò ńlá ńlá mú ní ìjọba ibile Ìbàràpá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
Àwọn ènìyàn Ìbàràpá tí jẹ oríṣiríṣi ìyá tí kò ṣé fẹnu ròyìn tán lọ́wọ́ àwọn ìka ẹ̀dá wọ̀nyí. Àbí báwo là tún ṣe fe ṣàpèjúwe àgbègbè tí kò tíì fojú bá ìdàgbàsókè kankan tàbí tọ́ka sí òun àmúyẹ kankan fún àìmọye ọdún. Bí ìjọba kan ṣé ń lọ ní òmíràn ń de síbẹ̀ orin kan náà ni gbogbo wọn ń kọ .
Ẹbí tani wàá ni bí ó ṣe àwọn jegúdú jerá olóṣèlú tí ó wà ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí.
Láfikún “Ìbàràpákan” nínú òṣèlú Ìbàràpá wáyé ní ìdìbò ilé ìgbìmò asòfin kékeré ni ọdún 2019.
Anthony tí kópa nínú ìbò lábé Asia Zenith Labour Party (ZLP), kété lẹ́yìn tí ó bá ìjákulẹ̀ pàdé nínú ìbò èyí tí ó bọ́ si ọwọ́ Hon. Saubana Ajibola Muraina tí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), lẹ́yìn èyí ní Ìbàràpákan ṣe ìkéde pé òun ti darapo mo ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógùn oṣù kẹta ọdún 2020. (March 15, 2020).
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pátápátá àti àwọn adarí wọn ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ àti agbègbè ni wọ́n ti fẹnu kò láti darapo mọ́ ẹgbẹ́ PDP tí ó wà lórí àlééfà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí tí àwọn tí se lórí ìjọba Seyi Makinde ẹniti o je Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ó sì ṣe iṣẹ́ takun-takun láàrin oṣù mẹ́wàá tí ó dé orí ipò.
“Ìpínlẹ̀ Oyo tí dára jù bí ó ṣe wá losu mewaa seyin lọ nísinsìnyí, àti ṣe tán láti fọwọ́ sowọ́ pò pelu ègbé PDP láti mú kí ìjọba awarawa túbọ̀ rọrùn sì fún gbogbo àwọn ènìyàn wá”. Díẹ̀ lára ìwé tí ó kó nìyí lọ́jọ́ tí ó dára pò mó egbe oselu PDP ní ọjọ́ keedogun oṣù kẹta ọdún 2020.
Lẹ́yìn bí oṣù kan tí ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ PDP ni ìròyìn kàn wípé Ìbàràpákan yóò di alága àjọ tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ omi ẹ̀rọ ni ipile Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ ajé, ogún jọ oṣù kẹrin ọdún 2020. ( April 20, 2020), láti ọwọ́ Gómìnà Seyi Makinde. Ìròyìn yíyàn sì ipò yí mú ínu àwọn ará ibarapa dùn gidi nítorí, wọn gbà pé, yiyan tí a yàn Ìbàràpákan kan si ipò yìí yóò mú kí ọ̀rọ̀ àìsí omi ẹ̀rọ di ohun ìgbàgbé ni àwọn ìlú Ìbàràpá lai mọ̀ pe òtúbánté nì.
Ní ìgbà kan ni odun 2020, Ìbàràpákan sọ wípé “ìjọba tí buwọ́ lú owó tí ó tó ọgọrun milionu náírà (100 million) láti yanjú ìpèníjà àìní omi ni àwon ìlú Ìbàràpá, owó náà tí wọnú ètò fún ọdún 2021,” a kú oriire ni Ìbàràpá “.
Nígbà tí Ìbéèrè wáyé lórí ọgọrun milionu yí kan náà ni ìpàdé ojúkojú tí àwọn ọ̀dọ̀ Ìbàràpá ṣe ni oṣù Kejo ọdún tó kọjá tí wón sì pe Ìbàràpákan kí ó wá jíhìn ìṣe ìríjú ẹ. Ṣùgbọ́n àwáwí oríṣiríṣi ni ó ń ṣe nínú ìpàdé náà.
Ìbéèrè ti o momi lọ́kàn àwọn ènìyàn ní: “nibo ni ọgọrun milionu tí Ìbàràpákan ni ìjọba tí buwọ́ lù láti gbà jáde ní ọdún 2021 wá?
Ǹjẹ́ èyí kò túmọ̀ sí pé ńṣe ni ó gbà owó náà tí ó sì ṣeé mọ́kun mọ̀kun?
Lẹ́yìn ọdún méjì sí, oro omi ẹ̀rọ ni ipilẹ Ọ̀yọ́ dàbí àlá tí kò lè ṣẹ ní Ìbàràpá.
Onírúurú Ìbéèrè ti àwọn ènìyàn sì ń bèèrè lórí oro omi tó wọn gogo bí ìmí eégún yí lọ ṣokùnfà bíbinu tí Honerebu Anthony Adebayo Adepoju ṣe bínú jáde ní orí gbongan Ibarapa Youth Summit WhatsApp pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà rè. Àwọn tí ó bínú jáde ní ojó náà ni Hon Peter Ojedokun ẹni tí ó jé ọkàn lára àwọn ọmọ ilé ìgbìmò asòfin fún ìjọba àrin gbùngbùn àti Àríwá Ìbàràpá. Hon Seun Fakorede ẹni tí ó jẹ Komisona fún àwọn ọ̀dó àti ère ìdárayá àti àwọn ogunlogo miran.
Lẹ́yìn tí Ìbàràpákan tí mo àpadé àti àlúdé òṣèlú agbegbe rẹ látàrí ajosepo rẹ pẹlu onimo èrò Seyi Makinde, Ìbàràpákan kò fi àkókò ṣòfò rárá láti kó àwọn dèdèwùrè àti àwọn aláìmòkan òdó sọ̀dí nítorí kò fẹ́ ẹni tí ó lè jẹ bí alátakò fún. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí ní gbà tikeeti fún wọn láti di ipò pàtàkì mú ní inú ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀.
Ní ọjọ́ tí òní, gbogbo àwọn alága ìjọba ìbílè meteeta àti ọgbọ́n kanselo tí ó wà lábé wọn ní wón jẹ́ aláàbọ̀ ẹ̀kọ́.
Gbogbo wa là rí ìwọ́de ìtìjú àti ìṣonu ni apa ariwa ìjọba ìbílè Ìbàràpá tí àwọn kánselo ṣe tí wọn wípé àwọn se afisun àwọn ìṣòro tó dojú kọ won fun Ìbàràpákan síbè tí kò gbé ìgbé ṣe kánkán lórí ẹ. Àwọn aláìmòkan èèyàn wonyi ni Ibarapakan gbé àkóso Ìbàràpá lé lówó, awon èèyàn yìí, ní yo ó sì lè ríi dájú pé òun ṣe oun kohun láti lọ láti fi mú erongba rè fún ìdíbo ọdún 2023 ṣe.
Ní gbogbo ọ̀nà ni Ìbàràpákan fi jẹbi èsùn tí ó fi kan Hon Muraina Ajibola. Lọ́jọ́ tí òní, nise ni Muraina dabi áńgẹ́lì bí a bá gbé àwọn méjèèjì sórí osunwon.
Lai dènà pẹnu, ká nipe Ìbàràpákan ni erongba gidi fún agbegbe ẹ èyí, tí ó fé je asójú e báyìí ni, yóò ti wá àwọn onílàákàyè ènìyàn fi sí orí aleefa dípò àwọn akí dani dání ẹ̀dá àti àwọn ọmọ ìta tí ó ń dá àlàáfíà agbegbe yí ru lọ.
Ó jé òun ti o báni nínú je gidi pé ọ̀rọ̀ òṣèlú agbegbe yí tí wàá di ọ̀rọ̀ àwàdà tí wọn fi ń mutí báyìí.
Ìbàràpákan kò bá dabi Mèsáyà ni ti ó bá jẹ nise ni ó lọ ipò rẹ àti ajosepo tí ó wà láàrin òun àti Gómìnà ìpílẹ̀ náà fún ìdàgbàsókè àgbègbè rẹ ni.
Lótìítọ́, Mèsáyà ni Ìbàràpákan jẹ́ fún àwọn ọ̀jẹ̀lú àti àwọn oníjekújẹ tí wọn ń wá ipò ni gbogbo ọ̀nà.
Ilẹ̀ Ìbàràpá tí wá rẹ̀bù ẹ̀yìn pátápátá lábé ìwà bàbá ìsàlẹ̀ tí Ìbàràpákan ń hù.
Ọkàn nínú àwọn òṣìṣẹ́ ìwé ìròyìn yí ni àwọn jàǹdùkú dá lọ́nà ni osu Kẹ̀wá ọdún tó kọjá yìí láti owó Ogbeni Adebayo Adepoju tí ó ní kí àwọn jàǹdùkú gbé oniroyin wa kí wọn dùn kooko mọ tí wọn sì tú èrò ìbánisòrọ̀ rẹ yewo. Gbogbo ìròyìn yí ni ó tẹ́ wá lọ́wọ́.
Lákòótán, atejade yí kìí se ògúlúútu tí a sọ mo Dókítà Anthony Adebayo Adepoju ṣùgbọ́n, ó yẹ kí àwọn ènìyàn Ìbàràpá mọ erongba Ìbàràpákan fún òṣèlú èyí tíì ṣe láti kó àwọn jàǹdùkú èyí tí yóò lè máa dárí jọ sórí oyè nígbà tí ìdàgbàsókè ìlú ń rẹyìn.
Isọwọ́ ṣe òṣèlú Ìbàràpákan kò lè sọ èso rere rárá bẹẹni afẹ́fẹ́ àlàáfíà kò le fẹ́ sí ìlú bí kò bá pe Àró àti Ọ̀dọ̀fin inú rẹ kì ó tún èrò ara rẹ̀ pá. Kí ó sì gbárùkù ti àwọn onímọ̀ ènìyàn tí ó nífẹ̀ẹ́ ará ìlú láti de orí ipò ìjọba.
Peoples Conscience, èrò wa ni wípé a kìí lẹ́ni ní mọsàn ká mú kíkan, bí wọn bá sì ń pè ènìyàn ní abìfun ràdàràdà ó yẹ kó pa ìfun ọ̀hún mọ́ díẹ̀.
Èrò
Ìlú Abínibí Àyándélé: Ìbàràpá Nínú Òkùnkùn Birimù-Birimù
Kìí ṣe ìròyìn mọ́ wípé àwọn olóṣèlú wa tí adìbò yàn àti àwọn tí wọ́n yàn sí ipò ní agbègbè Ìbàràpá ní ìpínlẹ̀ Òyó wọ́n ń wá ipò agbára fun ara wọn ni tí kìí ṣe ti ará ìlú.
Ìdí abájo ni wí pé ogúnlọ́gọ̀ ìyà ni àwọn ará agbègbè Ìbàràpá n jẹ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ní àwọn aṣojú lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ipò ìjọba.
Láì fọ̀rọ̀ Sábẹ́ ahọ́n sọ, a le sàkàwé Ìbàràpá pé ó jẹ́ agbègbè tí ó dà bí wípé kò sí asójú. Eléyí kìíse àsìso rárá bẹ́ẹ̀ sì ni kìí ṣe àhèsọ ọ̀rọ̀ mọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ará agbègbè Ìbàràpá n jẹ. Nínú àìṣedéédé yìí ni ọ̀nà tí kò dára tí ó tí di pàkúté íkú, ségesège ojú òpó ìbánisọ̀rọ̀, àisí ètò àbò tó péye àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.
Ìdùnnú ló jẹ́ fún àwọn árá agbègbè Ìbàràpá ní ìgbà tí wọ́n gbọ pé ọmọ wọn, Dókítà Olúsolá Àyándélé ti ra iná mọnàmáná ní ìwọ̀ oòrùn orílèède Nàíjírìa, ní èyí tó sí jẹ́ pé Ìbàràpá jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.
Bí oko kò bá jìnnà, ilá ibẹ̀ kìí kó, Kò pẹ́ rárá tí ó fi yé àwọn ará Ìbàràpá pé èróngbà wọn lórí íná mọ̀nàmáná pàbo ló já sí.
Báwo ni ati fẹ ṣe àlàyé ìlú tí kó ní iná mònàmánó fún òpòlopò osù? Kílódé tí awon alákòso Ibadan Electricity Distributing Company (IBEDC) tí n sé fi ìyà iná mònàmánó jẹ àwọn ará Ìbàràpá tó sì jẹ́ wípé Dókítà Àyándélé jẹ́ gbòógì nínú àwọn adárí ilé isé yì?.
Ìwádìí láti ọwọ Ìdèrè Update tí fi hàn dájúdájú wípé ìgbàkúgbà tí Dókítà Àyándélé bá wá sí Ìbàràpá ní àwọn ará ìlú má n fi ojú gánní iná. Kódà ọmọ oyún inú mọ èyí.
Ó ti wá di ohun à ń dájọ́ sí wípé odidi Ìbàràpá máa ń wà nínú òkùnkùn di ìgbà tí Sọlá bá wa ilé kó tó dí wípé wọ́n má rí iná mọ̀nàmáná lò. Ǹjẹ́ èyí kò ṣeni ní kàyéfí ní ìlú tó ní aṣọ tó ń wá ń wọ èkísà, ní ìlú tó lẹ́ran tó wá ń jeegun.
Tí ó bá jé wípé író ní ìwé ìròyìn yìí pa mọ́ wọn, kí awon àjọ IBEDC jáde síta láti wá se àlàyé fún àwọn ará ìlú, tàbí kí Dókítà Àyándélé wá tàn ìmólè sí òrò yí.
Èyí fi hàn kedere wípé Dókítà Àyándélé pẹ̀lú IBEDC wọn kó ní ìbọ̀wọ òun àkólékàn fún Ìbàràpá rárá.
Ìbánújé lójé àti fífi àkókò ṣòfò láti pe àwọn asojú wa ní ilé ìgbìmọ̀ aṣọ̀fin Ìpínlẹ̀ àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Àbújá láti wá fi ojú sùnùnkùn wo àìṣedéédé iná mọ̀nàmáná ní Ìbàràpá. Òpọ̀lọpọ̀ ìgbà kúkú ni àwọn ọ̀jẹ̀lú yí ti kọ èyìn sí àwọn ará ìlú tí ó sì jẹ́ wípé à tí dé ipò yí kò ṣe èyìn wọn. Kò sí ìgbà tí àwọn olóṣèlú yi ronú àti yọ àwọn ará ìlú wọn nínú làásìgbò kò sí iná, kò sí omi, kò sí ọ̀nà gidi, kò sí ilé ìwòsàn ìgbàlódé, kò sí ilé iṣé. Ìtìjú nlà gba ni èyí jẹ́.
Yàtò sí ipò aṣojú ilé ìgbìmọ̀ asòfin tí Dókítà Àyándélé ń jà fún, àwọn ará Ìbàràpá yí na ni wọ́n sá ṣe agbárùkù ti Èrùòbodò nígbà tí ó fi dù ipò Gómínà ní ọdún 2019. Ó jọ wípé Àyándélé náà ti darapọ̀ mọ́ àwọn olóṣèlú amúnisìn, aláìlòótọ́, tí kò ní ìbọ̀wọ̀ fún àwọn ará ìlú.
Ogúnlọ́gọ̀ àwọn ará ìlú yí ní wọ́n tí gbìyànjú láti mú òpin bá àìṣedéédé iná mọ̀nàmáná ní Ìbàràpá ní èyí tí ó sì jẹ́ wípé pàbo ní ìgbìyànjú wọn já sí.
Ní aàrin ọdún tí ó kọ já ní ọmọ ọkùnrin kan gbìyànjú láti gé ọwọ igi tí ó dàbò okùn iná tí àwọn IBEDC ní ohún ní o n ṣé okùnfà tí kò fi sí iná ní Ìbàràpá. Àwàdà keríkerí
Ìbánújé ló jẹ́ wípé àwọn IBEDC tí aní kí wọn fẹ́ wa lójú, ata ní wọ́n fi sẹ́nu. Ìwà jìbìtì ati ọgbọ́n àrekérekè ló pọ̀ lọ́wọ́ wọn . Ìwé owó iná ní wọn má n mú wá ní gbogbo ìgbà ní èyí tí kò sì sí iná.
Àwọn ará ìlú yí bákanà ní wọ́n máa n ra nkàn tí ó bá bàjẹ́ ní ara òpó iná.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà míràn ní iná máa n tàn ní ìlú Eruwa ọ̀kan nínú àwon ìlú méje ní agbègbè Ìbàràpá tí ó jẹ́ orípò àbójútó iṣẹ́ (service center IBEDC) ní èyí tí àwọn ìlú ìyókù màa ń wà ní òkùnkùn. Àsírí èyí tí kò ṣókùnkùn sáráàlú ní wípé ní ìwọ̀n ìgbà tí iná bà tí dé Eruwa, wọ́n á wá parọ́ wípé iná tí wá ní gbogbo Ìbàràpá méjèje.
Àwọn ìlú ìyókù máa wà ní òkùnkùn dí ìgbà tí Dókítà Àyándélé bá wá sí ilé fún òrò òsèlú tàbí ayeye.
Ìwádí tún fi han wípé ọwọ kunkun ni àwon àjo IBEDC fí n mú àwọn òsìsé wọn láti má pawó, tí won sí n kàn ní ipá fún wọn láti fi ọ̀nàkọnà gba owó lọ́wọ́ àwọn ará agbègbè Ìbàràpá.
Òpòlopò àwọn òṣìṣẹ́ yìí ní iṣẹ́ tí bọ́ lọ́wọ́ wọn nípasẹ̀ wípé wọn ó pawó wolé fún àjọ IBEDC. Báwo ní èèyàn ọlópólọ pípé má ṣe ń san owó iná tí won kó rí lò?.
Ká tí e ní wípé Àyándélé kò wá ní àti Ìbàràpá, sé àwon ará Ìbàràpá kó ní ẹ̀tọ́ sí iná ní? Ṣé a kò mọ̀ wí pé kó lè sí ìlọsíwájú ní ìlú tí kò sí iná mònàmánó ní?.
Tí iná bà kúkú wà, àwọn ará ìlú won kó sọ pé àwọn ó sanwó iná.
Ọdún mélòó ní IBEDC fe fi ìyà jẹ àwọn ará Ìbàràpá? Njé ale rí ẹni tí yóò gbà wà lè ní Ìbàràpá bá yí?.
-
Editorial2 years ago
N1M Scam Saga: Facts of The Matter in Public So Far
-
Uncategorized5 years ago
CAN asks FG to declare Miyetti Allah a terrorist organization
-
News4 years ago
Banabas’ Accusations: FIBSA President, Senate President react
-
Music4 years ago
JMW fastest rising Artist [BWEALTH] releases a single track for the Olu of Igboora in celebration of 1 year anniversary of enthronement
-
Encounters2 years ago
Kewulere blasts APC leaders, calls Muraina scammer, Ademola pretender
-
News3 years ago
Pa Patrick Adegbemi Was A Man of Uncommon Gestures, AOPE Council Chairman Mourns
-
News4 years ago
Hashtag #EndKidnappingInIbarapa Trends On Facebook And Whatsapp
-
News5 years ago
Facebook’s Supreme Court To Be Ready In Months